• About Us
    • Àtẹ́lẹwọ́ Podcast
  • Contact
  • Cookie Policy
  • Disclaimer
  • Privacy Policy
  • Sitemap
Freelanews
Advertisement
  • Home
  • News
    • Crime
  • Business
  • Brands
  • Banking
  • Opinion
  • Interview
  • Entertainment
  • Podcast
    • Àtẹ́lẹwọ́
  • Sports
  • Events
No Result
View All Result
  • Home
  • News
    • Crime
  • Business
  • Brands
  • Banking
  • Opinion
  • Interview
  • Entertainment
  • Podcast
    • Àtẹ́lẹwọ́
  • Sports
  • Events
No Result
View All Result
Freelanews
No Result
View All Result
Home General

Gbolohun lati owo aare ati olori ologun ni orile-ede Naijiria, Omowe Bola Ahmed Tinubu (Nikikun)

Rtn. Victor Ojelabi by Rtn. Victor Ojelabi
August 4, 2024
in General
0
Tinubu may suspend import duties on food, drugs
Total
0
Shares
Share 0
Tweet 0
Share 0
Share 0
Share 0
[dropcap]Ẹ[/dropcap]yin ara ilu mi, Mo n ba yin sọrọ loni pẹlu ọkan ti wiwo ati gege ojuṣe mi, ti o mọ nipa idamu ati awuyewuye ti o ti n ṣẹlẹ ni diẹ ninu awọn ipinlẹ wa.

Also read: One year not long enough for Tinubu’s policies to yield desired results – Senate

Pataki ninu awọn ti nfi ehunu won ni awọn ọdọ Naijiria ti o fẹ orilẹ-ede ti o dara julọ ati ti o si ni ilọsiwaju, nibiti awọn ala, ireti, ati awọn ifẹ ara ẹni wọn yoo ṣẹ.

Inu mi baje gidigidi nipa pipadanu awọn emi ni Borno, Jigawa, Kano, Kaduna ati awọn ipinlẹ miiran, iparun awọn ohun elo ara ilu ni diẹ ninu awọn ipinlẹ, ati ole jija ti ko ni lari ti awọn ile itaja, bi o ti jẹ pe awọn iṣakoso ikede sọ pe iṣafihan naa yoo jẹ alaafia. Iparun awọn ohun-ini naa jẹ ki a pada sẹyin gẹgẹ bi orilẹ-ede, nitoripe awọn ọrọ-aje ti a ni ni a o tun lo lati tun wọn ṣe.

Mo ba awon idile ati awọn ibatan ti awọn ti o ti ku ninu awọn iṣafihan naa kedun. A gbọdọ da ipaniyan, iwa-ipa ati iparun naa duro.

Gẹgẹ bi Aare orilẹ-ede yii, Mo gbọdọ rii daju pe ilu r’ogbo. Ni ibamu pẹlu ofin lati daabobo awọn emi ati ohun-ini gbogbo ara ilu, ijọba wa ko ni duro ti ọwọ ati jẹ ki diẹ ninu awọn ti o ni ero oṣelu lati fọ orilẹ-ede yii tu tu.

Nitori naa, mo ro awọn oniṣafihan ati awọn olori iṣakoso won lati dawọ iṣafihan eyikeyi duro, ki won si fi aaye sile fun ijiroro, eyi ti Mo ti fi ara mi fun ni gbogbo aye. Naijiria nilo gbogbo wa – laibikita ọjọ ori, ẹgbẹ, ẹsin tabi awọn iyatọ miiran, lati ṣiṣẹ pọ lati se ipin wa bi orilẹ-ede kan. Si awọn ti o ti lo anfaani ipo yii lati halẹ mo apakan orilẹ-ede yii, e j’awo: Ofin yoo de ọ. Ko si aaye fun ẹlẹyamẹya tabi halẹ ninu Naijiria ti a n wa lati kọ.

Nigbati a ba pa eto labe ofin gbogbo ara ilu mo ni ijọba yi o lọ siwaju. Awọn agbofinro wa gbodo rii daju lati da aabo kikun bo awọn ilu ati awọn ohun-ini awọn ara ilu ti ko ni ẹbi ni ọna ti o ni ojuṣe.

Erongba mi fun orilẹ-ede wa ni eyi ti o jẹ ododo ati ti o ni ilosiwaju nibiti gbogbo eniyan le gbadun alaafia, ominira, ati igbesi aye ti o ni itumọ ti ijọba awarawa nikan le pese – eyi ti o ni fi igbakan bo ikan ninu, ti o ni apawon ati ti yio si ma jise ti o to ati ti o ye awọn eniyan Naijiria.

Fun ọdun bi die seyin, eto-aje wa ti wa ni ailera ati o si dorikodo nitori ọpọlọpọ awọn idibajẹ ti o ti da ilọsiwaju wa duro. Bi odun kan sehin, orilẹ-ede wa ti de aaye nibiti a ko le tẹsiwaju lati ma lo awọn ojutu igba diẹ lati yanju awọn iṣoro igba pipẹ nitori eni ati awọn iran ti a ko ti bi. Mo gbe igbese ti o nira sugbon ti o se pataki lati yọ awọn idapada epo kuro ati lati fagilee ọpọlọpọ awọn ọna ti a gba se pasiparo owo naira si owo ilu okere eyiti o ti jẹ okun ni orun aje wa ati ti o ti da ilọsiwaju wa duro.

Awọn igbese wọnyi dènà iwa-ipa ati ere ti awọn obayeje ati jegudujera nje. Wọn tun dènà awọn idapada ti ko yẹ ti a ti fi fun awọn orilẹ-ede ti won sun mo wa ti o si mu iparun wa fun awọn eniyan wa ati aisan fun oro aje wa.

Awọn igbese wọnyi ti mo ṣe jẹ pataki ti a ba fe yi awọn ọdun ti iṣakoso aje ti ko ti ṣe wa ni rere pada. Bẹẹni, mo se tan lati f’aya di. Ṣugbọn mo le ṣe idaniloju fun yin pe ipinnu mi lati mu eto iṣakoso to muna doko ba awon eniyan o ni ye gere rara.

Ni awọn osu mẹrinla to kọja, ijọba wa ti ṣe awọn igbesẹ pataki ninu itukọ oro aje wa lati pese aaye fun ojo iwaju eyi ti yio kun fun opolopo ọrọ. Ni eto l’oro owo, awọn owo-ori ijọba lapapọ ti ju ilọpo meji lọ, o ti ju 9.1 trilionu Naira ni idaji akọkọ ti 2024 ti a ba fi we idaji akọkọ ti 2023 nitori awọn akitiyan nipa didi awon aaye inakuna, lilo ero adase, ati nina owo ni ọna ti o di ẹrù lori awọn eniyan. Ilosiwaju ti n wa diẹdiẹ ninu oro epo robi.

Ẹyin arakunrin ati arabinrin mi, ana wa ti jin die. Lati aaye ibiti orilẹ-ede wa ti na 97% owo ti a pa lori ati san gbese; a ti iyẹn dinku si 68% ni bi osu metala to kọja. A tun ti san awọn owo pasiparo ti o je ẹtọ ti o to $5 bilionu laiyi pa awon eto wa fun awon ara ilu lara.

Eyi ti si ti gba wa ni opolopo anfani ati aaye lati na owo pupo sii ori eyin ara ilu wa ati lati bu owo fun awọn iṣẹ awujọ pataki bi eto-ẹkọ ati ilera. O tun je ki awọn Ipinle ati awọn Ijọba Agbegbe leto si owo ti o gara ju lo l’ososu lati odo ijoba apapo ninu itan orile ede yi.

A ti tun bẹrẹ awọn iṣẹ amayederun pataki jake jado orilẹ-ede wa. A n ṣiṣẹ lati pari awọn iṣẹ ti a jogun ti o ṣe pataki si ilosiwaju aje wa, pẹlu awọn ọna, afara, awọn ọkọ oju-irin, agbara, ati awọn idagbasoke epo ati gaasi. Ni pataki, awọn iṣẹ ọna opopona eti okun Lagos si Calabar ati awọn iṣẹ ọna opopona Sokoto si Badagry yoo ṣii awọn ipinle merindilogun papo, ṣẹda ẹgbẹẹgbẹrun awọn iṣẹ ati itesiwaju ba iṣowo aje nipasẹ iṣowo, irin-ajo ati iṣọkan aṣa.

Iṣowo epo ati gaasi wa ti o ti n ṣubu tele ti gba itusile nipa awọn atunṣe ti mo kede ni osun karun odun ti a wa yi lati yanju awọn alafo ninu ofin ti o de Iṣẹ Epo (Petroleum). Ni oṣu to kọja, a ṣe awọn 1.61 milionu barasi epo fun ọjọ kan, ati awọn ohun-ini gaasi wa n gba akiyesi ti wọn yẹ. Awọn oludokoowo lati oke okun ti n pada, ati pe a ti rii idoko-owo lati odo awon oyinbo ti o kọja ẹgbẹẹgbẹrun bilionu dọla lati igba naa.

Eyin ara ilu mi, a jẹ orilẹ-ede ti o ni ọrọ pẹlu awọn orisun epo ati gaasi, ṣugbọn a ba orilẹ-ede ti o ti gbẹkẹle epo nikan, ti o ko ṣe akiyesi awọn orisun gaasi rẹ lati ṣe eto-aje. A si tun n lo awọn ogunlogo owo ilu okeere wa lati sanwo fun lilo re, ati idapada lilo rẹ. Lati yanju eyi, a ṣe ifilọlẹ Compressed Natural Gas Initiative (CNG) lati ri si eto irinna wa ati mu awọn idiyele wa silẹ. Eyi yoo je ki a ma pa tirilionu meji Naira mọ lo s’oṣu, ti a n lo lati gbe PMS ati AGO wọle ati fi aayey sile la na wo s’ori eto ilera ati eto-ẹkọ.

Fun idi eyi, a a ma pin awọn ohun elo miliọnu kan ti o ni idiyele kekere pupọ tabi ko ni rara si awọn ọkọ ilu ti o gbe awọn eniyan ati awọn ọja ti o nlo 80% ti PMS ati AGO ti a gbe wọle.

A ti bẹrẹ pinpin awọn ohun elo iyipada ati iṣeto awọn ile-iṣẹ iyipada moto elepo si gaasi (CNG) jakejado orilẹ-ede wa ni ifowosowopo pẹlu awon aladani. A gbagbọ pe iṣe CNG yii yoo di awọn idiyele owo oko bii ida 60 ati pe yio tu dènà bi nkan se gbowo lori.

Ijọba wa ti fi ifaramo rẹ han si awọn ọdọ nipa eto awin ẹkọ. L’oni, 45.6 bilionu naira ni a ti s’eto re fun sisan fun awon akeko ati awọn ile-ẹkọ wọn.

Yi o wu mi l’ori pupo ti awọn ọdọ ba le lo anfani awin ẹkọ yii. A tun ti fi idi Consumer Credit Corporation mu le pẹlu N200 bilionu lati ṣe iranlọwọ fun awọn ara ilu lati gba awọn ọja pataki laisi iwulo fun sisanwo owo lẹsẹkẹsẹ, eleyi yio mu aye rorun fun miliọnu awọn ara ilu. Eyi yoo tun di jiji owo lai leto ku. Ni ọsẹ yii, mo ti paṣẹ afikun 50 bilionu naira kọọkan fun NELFUND – awin ẹkọ, ati Ẹka Credit Corporation lati inu owo ti a gba pada nipasẹ EFCC.

Ni afikun, a ti ni $620 milionu labẹ Isakoso Digital ati Creative (IDiCE) – eto kan lati fun awọn ọdọ wa ni agbara, ṣẹda awọn miliọnu awọn iṣẹ IT ati imọ-ẹrọ ti yoo mu won b’egbe pe ni agbaye. Awọn eto wọnyi pẹlu eto Talents Technical Talents ti o kọja milionu mẹta. O s’eni laanu wipe ọkan ninu awọn ile-iṣẹ ti won yio lo ni awon tifi ehunu won han bajẹ lakoko ṣafihan ni ilu Kano. Itiju nla!

Ni afikun, a ti ṣafihan Eto Imọ-jinlẹ Artisans (SUPA); Ile-ẹkọ giga Awon Odo (NIYA); ati Eto National Youth Talent Export Programme (NATEP).

Pẹlupẹlu, owo ti o ju N570 bilionu lọ ni a ti fun awon gomina yin ki won fun yin lati mu igbesi aye eyin ara ilu rogbo, ati pe awon onise ada ni ti o ju 600,000 ni o je anfaani owo isuna fun awon onisẹ kereje kereje. A si nireti pe laipẹ 400,000 awon onise kereje kereje yoo ni anfani bẹ pẹlu.

Ni afikun, awọn ara ilu bi 75,000 ti setan lati gba awin milionu kan kan ti o bẹrẹ ni oṣu yii. A tun ti kọ awọn ile-iṣẹ MSME mẹwa laarin ọdun ti o ti kọja, ati ṣẹ da awọn iṣẹ 240,000 nipasẹ wọn ati wipe awọn ile-iṣẹ marun miran si wa ti a o ti ko tan ti o ba di osu kewa ọdun yii.

Sisanwo 1 bilionu naira kọọkan fun awon aladani nla labẹ awin single-digit lati mu itesiwaju ati idagbasoke ba iṣe won.

Mo buwọlu ile l’ori owo awon osise ni ọsẹ to kọja, nibayi N70,000 ni owo ti awọn oṣiṣẹ ti o gba owo ti o kere ju fun oṣu kan.

Oṣu mẹfa sẹyin ni Karsana, Abuja, mo ṣe igbekalẹ ipele akọkọ ti eto ile gbigbe, Renewed Hope City and Estate. Igbese yii je akọkọ ti iru mẹfa ti a ti pinnu jakejado ekun mefa orilẹ-ede yi. Ori kankan eto yi ni yi o si ni o kere ju 1,000 ile, pẹlu Karsana funrararẹ ti o ni eto ile 3,212.

Ni afikun si awọn iṣẹ ilu wọnyi, a tun ṣe ifilọlẹ Renewed Hope Estates ni gbogbo ipinlẹ, kọọkan pẹlu awọn ile 500. Ero wa ni lati pari apapọ awọn ile 100,000 ni wọn ọdun mẹta to n bọ. Awon ise yii kii ṣe lati pese awọn ile gbigbe nikan ṣugbọn lati ṣẹda ẹgbẹẹgbẹrun awọn iṣẹ ni gbogbo orilẹ-ede ati imudara idagbasoke aje.

A tu ti n pese awọn iwuri fun awọn agbe wa lati ki ounje le po yanturu ni idiyele. Mo si ti paṣẹ pe ki a yo awọn afikun owo-ori ti o wa lori iresi, alikama, agbado, sorghum, awọn oogun, ati awọn ipese oogun ati iṣoogun fun osu mẹfa to n bọ, lati mu edinwo ba awon nkan wonyi.

Mo ti n ba awọn gomina wa ati awọn minisita pataki sọrọ l’ori opo ounje fun awon ara ilu. A ti pin awọn ajile. Ero wa ni lati da’ko lori ilẹ ti o ju miliọnu mẹwa hectares lati gbin awon nkan ti a n jẹ. Ijọba apapo yoo pese gbogbo awọn iwuri ti a nilo fun iṣẹ akanṣe yii, nigbati ijoba ipinle pese ilẹ, eyiti yoo pe se ise fun ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan wa, yi o si tun mu ounje po si fun awon ara ilu. Ni awọn osu diẹ ti o kọja, a tun ti sanwo fun awọn ẹrọ ise oko sise bi tractor ati planter, ti o lo bi bilionu Naira lati United States, Belarus, ati Brazil. Mo le jẹrisi fun ọ pe awọn ohun elo naa wa ni ọna.

Ẹyin ara ilu Naijiria, paapaa eyi ọdọ wa, mo ti gbọ yin yekeyeke. Irora ati ibanujẹ okan ti e fi nse awon iṣafihan wọnyi ye mi, sugbon mo fẹ fi da yin l’oju pe ijọba wa ti pinnu lati gbọ ati yanju awọn aibalẹ okan yin.

Ṣugbọn a ko gbọdọ gba iwa-ipa ati iparun laaye lati fa orilẹ-ede wa ya perepere. A ni lati ṣiṣẹ pọ lati kọ ọjọ iwaju ti o dara julọ, nibiti gbogbo omo Naijiria le gbe pẹlu ọla ati ilosiwaju.

Ajose ni Iṣẹ ti o wa niwaju wa jẹ, emi ni si n dari igbejade re gẹgẹ bi Aare yin. Ọpọlọpọ iṣẹ ni a ti se lati mu oro aje wa iduroṣinṣin ati wipe mi o gbọdọ ni idojukọ lati rii daju pe awọn anfani naa de ọdọ gbogbo mutumuwa ile Naijiria gẹgẹ bi ileri.

Ijọba mi n ṣiṣẹ takuntakun lati mamu gbooro ba awon nkan amayederun l’orilẹ-ede wa ati ṣẹda awọn anfaani pupo fun awọn ọdọ wa.

Ma se jẹ ki ẹnikẹni ko parọ, kọ ọ lodi si orilẹ-ede rẹ tabi sọ fun ọ pe ijọba rẹ ko bikita fun ọ. Botilẹjẹpe ọpọlọpọ igba ni ireti ti dopin ni awon ijoba to koja, igba tuntun ti de, Renewed Hope. A n ṣiṣẹ takuntakun nitori yin, laipe awọn ojulowo abajade naa yio farahan lati rii ati lati gbadun.

Jẹ ki a ṣiṣẹ pọ lati kọ ọjọ iwaju ti o dara julọ fun ara wa ati fun awọn iran ti nbọ. E je ki a faaye gba ireti ju ibẹru lọ, iṣọkan ju pipin lọ, ati ilọsiwaju ju idaduro lọ. Eto-aje n ngbera lọwọ; jọwọ, maṣe dina rẹ. Niwon igba ti a ti ngbadu iṣakoso ijọba tiwantiwa fun ọdun mejidilogbon bo, ma jẹ ki awọn ọta ijọba tiwantiwa lo ọ lati ṣe agbejade ero ti ko ni ofin ti yoo da wa pada ni irin-ajo ijọba tiwantiwa wa. Iwaju la wa nlo, o ni pada sehin!

Ni ipari, awọn alaṣẹ aabo yio tẹsiwaju lati mojuto alaafia, ofin, ati irowo irose ni orilẹ-ede wa ni ibamu pẹlu awọn akọle ti o yẹ lori awọn ẹtọ ara ilu, eyiti Naijiria jẹ alabaṣiṣẹpọ. Aabo gbogbo awọn ara ilu Naijiria se pataki.

Ọlọrun ṣeun – ati O ṣeun fun ibara ba le yin, ati pe ki Ọlọrun tẹsiwaju lati bukun orilẹ-ede nla wa. O ṣeun pupọ.

Total
0
Shares
Share 0
Tweet 0
Share 0
Share 0
Share 0
otunba victor profile picture scaled
Rtn. Victor Ojelabi

Ojelabi, the publisher of Freelanews, is an award winning and professionally trained mass communicator, who writes ruthlessly about pop culture, religion, politics and entertainment.


Discover more from Freelanews

Subscribe to get the latest posts sent to your email.

Related Posts

Throw out foods in fridge after four-hour power outage, says WHO
General

Throw out foods in fridge after four-hour power outage, says WHO

by Quadri Olaitan
June 7, 2024
Untitled 1 5
General

‘Our nation needs your supports’ Baba Adinni of Yewaland celebrates Muslims, preaches peace

by Freelanews
May 13, 2021
WhatsApp Image 2021 03 03 at 10.52.07 AM 1
General

‘African giant’ Burna Boy to perform at 2021 Grammy

by Freelanews
March 3, 2021
Katsina State Givernor aminu bello masari
General

‘Fight back’ Get arms to defend yourselves, Gov Masari tells citizens

by Freelanews
August 17, 2021
Fani Kayode 1
General

‘Don’t be a slave!’ FFK slams Ogun governor over Dangote

by Freelanews
April 8, 2020

Discussion about this post

ADVERTISEMENT

Recent News

Makinde

Makinde receives strong push for 2027 presidential bid

October 8, 2025
Rotary Club cataract surgery

Rotary Club cataract surgery transforms 30,000 lives

October 8, 2025
Ikechukwu N arrest

Ikechukwu N arrest shocks Argentina after INTERPOL raid

October 8, 2025
CBN monetary stability

CBN assures Nigerians of monetary stability progress

October 8, 2025

Search

  • Trending
  • Comments
  • Latest
Political persecution in Ogun State

Political persecution in Ogun State: Abiodun moves against Otunba Gbenga Daniel with demolition threats again

August 9, 2025
Abdul-Muiz Olanrewaju Animashaun

Abdul-Muiz Olanrewaju Animashaun remembered with love

September 14, 2025
Taylor Swift deepfake scandal

Taylor Swift faces deepfake scandal as Swifties call for stricter regulation

January 25, 2024
April Wind Couture

April Wind Couture thrives in Nigeria’s tough economy with bold Ankara vision

September 12, 2025
amoke

‘Meals by Amoke’ We serve traditional dishes in a modern way, Bukoye Fasola reveals

0
Image 2024 03 26 at 120645 AM jpeg

Charles Inojie, Ali Nuhu call on communities to #MakeWeHalla against domestic violence

0
Meran Primary Health Centre

Lagos father shares heartbreaking experience at Meran Primary Health Centre (Photos)

0
fls2

‘Disarticulated system’ Gov’t confused about Nigerian education, expert laments

0
Makinde

Makinde receives strong push for 2027 presidential bid

October 8, 2025
Rotary Club cataract surgery

Rotary Club cataract surgery transforms 30,000 lives

October 8, 2025
Ikechukwu N arrest

Ikechukwu N arrest shocks Argentina after INTERPOL raid

October 8, 2025
CBN monetary stability

CBN assures Nigerians of monetary stability progress

October 8, 2025
October 2025
MTWTFSS
 12345
6789101112
13141516171819
20212223242526
2728293031 
« Sep    
Freelanews

Freelanews is a Nigerian digital news platform that delivers timely, credible, and engaging stories across politics, business, entertainment, lifestyle, and the creative industry, with a strong focus on promoting innovation, integrity, and inclusivity in storytelling.

Follow Us

  • Facebook
  • TikTok
  • YouTube
  • Instagram

Editor’s Pick

  • OGD vs DA
    OGD vs DA: The real story never told
    • August 22, 2025
  • Toyota Sienna harassment
    Why is Lagos State govt harassing Toyota Sienna users?
    • August 19, 2025
  • Otunba Gbenga Daniel
    Who really is Otunba Gbenga Daniel?
    • August 18, 2025

Hot!

Makinde

Makinde receives strong push for 2027 presidential bid

October 8, 2025
Rotary Club cataract surgery

Rotary Club cataract surgery transforms 30,000 lives

October 8, 2025
No Result
View All Result
  • About Us
  • Contact
  • Advertisement
  • Sitemap

© 2025 Freelanews | by Iretura.

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password?

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In

Add New Playlist

Total
0
Share
0
0
0
0
0
0
No Result
View All Result
  • Home
  • News
    • Crime
  • Business
  • Brands
  • Banking
  • Opinion
  • Interview
  • Entertainment
  • Podcast
    • Àtẹ́lẹwọ́
  • Sports
  • Events

© 2025 Freelanews | by Iretura.

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.

Discover more from Freelanews

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading